Matthew 27:57-61

A tẹ́ Jesu sínú ibojì

57 aNígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, 58lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un. 59Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í. 60Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnrarẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ. 61Maria Magdalene àti Maria kejì wà níbẹ̀, wọn jókòó òdìkejì ibojì náà.

Copyright information for YorBMYO